2 Timothy 2:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ẹnikẹ́ni bá wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò ninu àwọn nǹkan wọnyi, olúwarẹ̀ yóo di ohun èèlò tí ó níye lórí, tí a yà sọ́tọ̀, tí ó wúlò fún baálé ilé. Yóo di ẹni tí ó ṣetán láti ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ rere.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ẹnikẹni ba wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́ kuro ninu wọnyi, on ó jẹ ohun èlo si ọlá, ti a yà si ọ̀tọ, ti o si yẹ fun ìlo bãle, ti a si ti pèse silẹ si iṣẹ rere gbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ẹnìkẹni bá wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìwọ̀nyí, òun yóò jẹ́ ohun-èlò sí ọlá, tí a yà sọ́tọ̀, tí ó sì yẹ fún ìlò baálé, tí a sì ti pèsè sílẹ̀ fún iṣẹ́ rere gbogbo.