2 Timothy 4:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí mo níláti jà fún ara mi ní ẹẹkinni, kò sí ẹni tí ó yọjú láti gbèjà mi: gbogbo wọn ni wọ́n fi mí sílẹ̀. Kí Ọlọrun má kà á sí wọn lọ́rùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li àtetekọ jẹ ẹjọ mi, kò si ẹniti o bá mi gba ẹjọ ro, ṣugbọn gbogbo enia li o kọ̀ mi silẹ: adura mi ni ki a máṣe kà a si wọn li ọrùn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àkọ́kọ́ jẹ́ ẹjọ́ mi, kò sí ẹni tí ó ba mi gba ẹjọ́ rò ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn ni o kọ̀ mi sílẹ̀: Àdúrà mi ni kí a má ṣe ká à sí wọn lọ́rùn.