2 Timothy 4:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Oluwa dúró tì mí, ó fún mi lágbára tí mo fi waasu ìyìn rere lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, tí gbogbo àwọn tí kì í ṣe Juu fi gbọ́. Bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe bọ́ lẹ́nu kinniun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Oluwa gbà ẹjọ mi ro, o si fun mi lagbara; pe nipasẹ mi ki a le wãsu na ni awàjálẹ̀, ati pe ki gbogbo awọn Keferi ki o le gbọ́: a si gbà mi kuro li ẹnu kiniun nì.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Olúwa gba ẹjọ́ mi rò, ó sì fún mi lágbára; pé nipasẹ̀ mi kí a lè wàásù náà ní àwàjálẹ̀, àti pé kí gbogbo àwọn aláìkọlà lè gbọ́; a sì gbà mí kúrò lẹ́nu kìnìún náà.