2 Timothy 4:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àkókò ń bọ̀ tí àwọn eniyan kò ní fẹ́ fetí sí ẹ̀kọ́ tí ó yè. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara wọn ni wọn yóo tẹ̀lé, tí wọn yóo kó àwọn olùkọ́ tira, tí wọn yóo máa sọ ohun tí wọn máa ń fẹ́ gbọ́ fún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe ìgba yio de, ti nwọn kì yio le gba ẹkọ́ ti o yè kõro; ṣugbọn bi nwọn ti jẹ ẹniti eti nrìn nwọn ó lọ kó olukọ jọ fun ara wọn ninu ifẹkufẹ ara wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé ìgbà yóò dé, tí wọn kì yóò lè gba ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti jẹ́ ẹni tí etí ń rin, wọn ó lọ kó oluko jọ fún ara wọn nínú ìfẹ́kùfẹ́ ara wọn.