2 Timothy 4:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nisinsinyii adé òdodo náà wà nílẹ̀ fún mi, tí Oluwa onídàájọ́ òdodo yóo fún mi ní ọjọ́ náà. Èmi nìkan kọ́ ni yóo sì fún, yóo fún gbogbo àwọn tí wọn ń fi tìfẹ́tìfẹ́ retí ìfarahàn rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati isisiyi lọ a fi ade ododo lelẹ fun mi, ti Oluwa, onidajọ ododo, yio fifun mi li ọjọ na, kì si iṣe kìki emi nikan, ṣugbọn pẹlu fun gbogbo awọn ti o ti fẹ ifarahàn rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti ìsinsinyìí lọ a fi adé òdodo lélẹ̀ fún mi, tí Olúwa onídàjọ́ òdodo, yóò fífún mi ni ọjọ́ náà kì í sì í ṣe kìkì èmi nìkan ṣùgbọ́n pẹ̀lú fún gbogbo àwọn tí ó ti fẹ́ ìfarahàn rẹ̀.