Acts 1:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n pada sí Jerusalẹmu láti orí òkè tí à ń pè ní Òkè Olifi. Òkè náà súnmọ́ Jerusalẹmu, kò tó ibùsọ̀ kan sí ìlú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni nwọn pada ti ori òke ti a npè ni Olifi lọ si Jerusalemu, ti o sunmọ Jerusalemu ni ìwọn ìrin ọjọ isimi kan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn náà ni wọ́n padà sí Jerúsálému láti orí òkè ti a ń pè ni Ólífì, tí ó tó ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ ìsinmi kan.