Acts 1:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n wọ inú ilé, wọ́n lọ sí iyàrá òkè níbi tí wọn ń gbé. Àwọn tí wọ́n jọ ń gbé ni Peteru, Johanu, Jakọbu, Anderu, Filipi, Tomasi, Batolomiu, Matiu, Jakọbu ọmọ Alfeu, Simoni ti ẹgbẹ́ Seloti ati Judasi ọmọ Jakọbu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn si wọle, nwọn lọ si yara oke, nibiti Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu, ati Anderu, ati Filippi, ati Tomasi, Bartolomeu, ati Matiu, Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Simoni Selote, ati Juda arakunrin Jakọbu, gbe wà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọn sì wọlé, wọn lọ sí ìyàrá òkè, níbi tí wọ́n ń gbé. Àwọn tó wà níbẹ̀ ni Pétérù, àti Jákọ́bù àti Jòhánù, àti Áńdérù, àti Fílípì, àti Tọ́másì, Bátóléméù, àti Mátíù, Jákọ́bù ọmọ Álíféù, àti Símónì Sélótì, àti Júdà arakùnrin Jákọ́bù.