Acts 1:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nítorí náà, ẹ̀tọ́ ni kí á yan ẹnìkan ninu àwọn tí ó ti wà pẹlu wa ní gbogbo àkókò tí Jesu Oluwa ti ń wọlé, tí ó ń jáde pẹlu wa, láti àkókò tí Johanu ti ń ṣe ìrìbọmi títí di ọjọ́ tí a fi mú Jesu kúrò lọ́dọ̀ wa, kí olúwarẹ̀ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí ajinde Jesu, kí ó sì di ọ̀kan ninu wa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ninu awọn ọkunrin wọnyi ti nwọn ti mba wa rìn ni gbogbo akoko ti Jesu Oluwa nwọle, ti o si njade lãrin wa,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, ó di dandan láti yan ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin wọn tí wọn ti ń bá wa rìn ni gbogbo àkókò tí Jésù Olúwa ń wọlé, tí ó sì jáde láàrin wa.