Acts 1:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn aposteli yìí ni ó fi ara rẹ̀ hàn láàyè lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀ pẹlu ẹ̀rí tí ó dájú. Wọ́n rí i níwọ̀n ogoji ọjọ́, ó sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tí ó jẹ mọ́ ti ìjọba Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ẹniti o si farahàn fun lãye lẹhin ìjiya rẹ̀ nipa ẹ̀rí pupọ ti o daju, ẹniti a ri lọdọ wọn li ogoji ọjọ ti o nsọ ohun ti iṣe ti ijọba Ọlọrun:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀, ó fi ara rẹ̀ hàn fún wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí tí ó dájú pé òun wà láàyè. Ó fi ara hàn wọ́n fún ogójì ọjọ́, ó sì sọ̀rọ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run.