Acts 10:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìran tí Peteru rí yìí rú u lójú. Bí ó ti ń rò ó pé kí ni ìtumọ̀ ohun tí òun rí yìí, àwọn tí Kọniliu rán sí i ti wádìí ibi tí ilé Simoni wà, wọ́n ti dé ẹnu ọ̀nà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o si ti ngọ́ Peteru ninu ara rẹ̀ bi a ba ti mọ̀ iran ti on ri yi si, si wo o, awọn ọkunrin ti a rán ti ọdọ Korneliu wá de, nwọn mbère ile Simoni, nwọn duro li ẹnu-ọ̀na,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí Pétérù sì ti ń dààmù nínú ara rẹ̀ bí a ìbá ti mọ̀ ìran tí oun ri yìí sí, si wò ó, àwọn ọkùnrin tí a rán wá láti ọ̀dọ̀ Kọ̀nélíù dé. Wọ́n ń bèèrè ilé Símónì, wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà.