Acts 10:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, ranṣẹ lọ sí Jọpa, kí o lọ pe Simoni tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Peteru wá. Ó dé sílé Simoni tí ń ṣe òwò awọ, létí òkun.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ ranṣẹ lọ si Joppa, ki o si pè Simoni wá, ẹniti apele rẹ̀ jẹ Peteru; o wọ̀ ni ile Simoni alawọ leti okun: nigbati o ba de, yio sọ̀rọ fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ ránsẹ́ lọ sí Jópà, kí ó sì pe Símónì wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Pétérù; ó wọ̀ ní ilé Símónì aláwọ léti òkun: nígbà ti ó bá dé, ẹni yóò sọ̀rọ̀ fún ọ.’