Acts 10:37 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní gbogbo Judia. Ó bẹ̀rẹ̀ láti Galili lẹ́yìn ìrìbọmi tí Johanu ń sọ pé kí àwọn eniyan ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin na mọ̀ ọ̀rọ na ti a kede rẹ̀ yiká gbogbo Judea, ti a bẹ̀rẹ si lati Galili wá, lẹhin baptismu ti Johanu wasu rẹ̀;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin náà mọ ọ̀rọ̀ náà tí a kéde rẹ̀ yíká gbogbo Jùdíà, tí a bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ láti Gálílì, lẹ́yìn bamitíìsímù ti Jòhánù wàásù rẹ̀.