Acts 11:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó mú mi ranti ọ̀rọ̀ Oluwa nígbà tí ó sọ pé, ‘Omi ni Johanu fi ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fun yín, ṣugbọn Ẹ̀mí Mímọ́ ni a óo fi ṣe ìwẹ̀nùmọ́ yín.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni mo ranti ọ̀rọ Oluwa, bi o ti wipe, Johanu fi omi baptisi nitõtọ; ṣugbọn a o fi Ẹmí Mimọ́ baptisi nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni mo rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí pé, ‘Jòhánù fi omi bamitíìsì nítóòtọ́; ṣùgbọ́n a ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitíìsì yín.’