Acts 11:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn tí ó túká nígbà inúnibíni tí ó ṣẹlẹ̀ ní àkókò Stefanu dé Fonike ní Kipru ati Antioku. Wọn kò bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ ìyìn rere àfi àwọn Juu nìkan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina awọn ti a si tuka kiri niti inunibini ti o ṣẹ̀ niti Stefanu, nwọn rìn titi de Fenike, ati Kipru, ati Antioku, nwọn kò sọ ọ̀rọ na fun ẹnikan, bikoṣe fun kìki awọn Ju.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà àwọn tí a sì túká kiri ní ti inúnibíni tí ó dìde ní ti Sítéfánù, wọ́n rìn títí de Fonísíà, àti Kípíru, àti Ańtíókù, wọn kò sọ ọ̀rọ̀ náà fún ẹnìkan bí kò ṣe fún kìkì àwọn Júù.