Acts 11:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó rí i, ó mú un wá sí Antioku; fún ọdún kan gbáko ni àwọn mejeeji fi wà pẹlu ìjọ, tí wọn ń kọ́ ọpọlọpọ eniyan lẹ́kọ̀ọ́. Ní Antioku ni a ti kọ́ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Kristi ní “Kristẹni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si ri i, o mu u wá si Antioku. O si ṣe, fun ọdun kan gbako ni nwọn fi mba ijọ pejọ pọ̀, ti nwọn si kọ́ enia pipọ. Ni Antioku li a si kọ́ pè awọn ọmọ-ẹhin ni Kristian.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nígbà tí ó sì rí i, ó mú un wá sí Áńtíókù. Fún ọdún kan gbáko ni wọ́n fi ń bá ìjọ péjọ pọ̀, tí wọ́n sì kọ́ ènìyàn púpọ̀. Ní Áńtíókù ni a sì kọ́kọ́ ti pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni “Kírísítìánì.”