Acts 11:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀kan ninu wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Agabu bá dìde. Ẹ̀mí gbé e láti sọ pé ìyàn ńlá yóo mú ní gbogbo ayé. (Èyí ṣẹlẹ̀ ní ayé ọba Kilaudiu.)
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ọkan ninu wọn, ti a npè ni Agabu si dide, o tipa Ẹmi sọ pe, ìyan nla yio mu ká gbogbo aiye: eyiti o si ṣẹ li ọjọ Klaudiu Kesari.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn, ti a ń pè ni Ágábù sí dìde, ó ti ipa Ẹ̀mí sọ pé, ìyàn ńlá yóò mú yíká gbogbo ilẹ̀ Róòmù. (Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà ìsèjọba Kíláúdíù.)