Acts 11:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹẹkeji ohùn náà tún wá láti ọ̀run. Ó ní, ‘Ohunkohun tí Ọlọrun bá ti sọ di mímọ́, ìwọ kò gbọdọ̀ pè é ní aláìmọ́ mọ́.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ohùn kan dahun lẹ̃keji lati ọrun wá pe, Ohun ti Ọlọrun ba ti wẹ̀nu, iwọ máṣe pè e li èwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣùgbọ́n ohùn kan dáhùn nígbà ẹ̀ẹ̀kéjì láti ọ̀run wá pé, ‘Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀mọ́, kí ìwọ má ṣe pè é ní àìmọ́.’