Acts 12:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n kọjá ẹ̀ṣọ́ kinni ati ekeji, wọ́n wá dé ẹnu ọ̀nà ńlá onírin tí ó jáde sinu ìlú. Fúnra ìlẹ̀kùn yìí ni ó ṣí sílẹ̀ fún wọn. Wọ́n bá jáde sí ojú ọ̀nà kan. Lójú kan náà, angẹli bá rá mọ́ Peteru lójú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn kọja iṣọ ikini ati keji, nwọn de ẹnu-ọ̀na ilẹkun irin, ti o lọ si ilu, ti o si tikararẹ̀ ṣí silẹ fun wọn: nigbati nwọn si jade, nwọn nlọ titi li ọ̀na igboro kan; lojukanna angẹli na si fi i silẹ lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n kọjá ìṣọ́ ìkínní àti ìkejì, wọ́n dé ẹnu-ọ̀nà ìlẹ̀kùn irin tí ó lọ sí ìlú. Ó sí tikararẹ̀ sí sílẹ̀ fún wọn: wọ́n sì jáde, wọ́n ń gba ọ̀nà ìgboro kan lọ; lójúkan náà ańgẹ́lì náà sì fi í sílẹ̀ lọ.