Acts 12:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Hẹrọdu wá Peteru títí, ṣugbọn kò rí i. Lẹ́yìn tí ó ti wádìí lẹ́nu àwọn ẹ̀ṣọ́ tán, ó ní kí wọ́n pa wọ́n. Ni Hẹrọdu bá kúrò ní Judia, ó lọ sí Kesaria, ó lọ gbé ibẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Herodu si wá a kiri, ti kò si ri i, o wádi awọn ẹ̀ṣọ, o paṣẹ pe, ki a pa wọn. O si sọkalẹ lati Judea lọ si Kesarea, o si joko nibẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Héródù sì wá a kiri, tí kò sì rí i, ó wádìí àwọn ẹ̀sọ́, ó paṣẹ pé, kí a pa wọ́n. Hẹ́rọ́dù sì sọ̀kalẹ̀ láti Jùdíà lọ sí Kesaríà, ó sì wà níbẹ́ fún ìgbà díẹ̀.