Acts 12:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Inú bí Hẹrọdu pupọ sí àwọn ará Tire ati Sidoni. Àwọn ará ìlú wọnyi bá fi ohùn ṣọ̀kan, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n tu Bilasitu tíí ṣe ìjòyè ọba tí ó ń mójútó ààfin lójú, wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ pé kí ọba má bínú sí àwọn nítorí láti ilé ọba ni wọ́n ti ń rí oúnjẹ jẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Herodu si mbinu gidigidi si awọn ara Tire on Sidoni: ṣugbọn nwọn fi ọkàn kan wá sọdọ rẹ̀, nigbati nwọn si ti tu Blastu iwẹfa ọba loju, nwọn mbẹbẹ fun alafia; nitori lati ilu ọba lọ li a ti mbọ́ ilu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Héródù sí ń bínú gidigidi sí àwọn ará Tírè àti Sídónì; ṣùgbọ́n wọ́n fi ìmọ̀sọ̀kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí wọn sì ti tu Bílásítù ìwẹ̀fà ọba lójú, wọn ń bẹ̀ẹ̀ fún àlàáfíà, nítorí pé ìlú ọba náà ni ìlú tiwọn ti ń gba oúnjẹ.