Acts 12:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní òru, mọ́jú ọjọ́ tí Hẹrọdu ìbá mú Peteru wá fún ìdájọ́, Peteru sùn láàrin àwọn ọmọ-ogun meji, wọ́n fi ẹ̀wọ̀n meji dè é; àwọn ọmọ-ogun kan sì tún wà lẹ́nu ọ̀nà, tí wọn ń ṣọ́nà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Herodu iba si mu u jade, li oru na Peteru sùn li arin awọn ọmọ-ogun meji, a fi ẹ̀wọn meji de e, ẹ̀ṣọ́ si wà li ẹnu-ọ̀na, nwọn nṣọ́ tubu na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní òru náà gan-an ti Héródù ìbá sì mú un jáde, Pétérù ń sùn láàrin àwọn ọmọ-ogun méjì, a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é, ẹ̀sọ́ sí wà lẹ́nu-ọ̀nà, wọ́n ń ṣọ́ túbú náà.