Acts 12:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ni Peteru bá tẹ̀lé e jáde. Kò mọ̀ pé òtítọ́ ni ohun tí ó ti ọwọ́ angẹli náà ṣẹlẹ̀, ó ṣebí àlá ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si jade, o ntọ̀ ọ lẹhin; kò si mọ̀ pe otitọ li ohun na ṣe lati ọwọ́ angẹli na wá; ṣugbọn o ṣebi on wà li ojuran.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pétérù sì jáde, ó ń tọ ọ lẹ́yìn; kò sí mọ̀ pé ohun tí a ṣe láti ọwọ́ ańgẹ́lì náà jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n ó ṣèbí òun wà lójú ìran.