Acts 13:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn wolii ati àwọn olùkọ́ wà ninu ìjọ tí ó wà ní Antioku. Ninu wọn ni Banaba ati Simeoni tí wọn ń pè ní Adúláwọ̀ wà, ati Lukiusi ará Kirene, ati Manaeni tí wọ́n jọ tọ́ dàgbà pẹlu Hẹrọdu baálẹ̀, ati Saulu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
AWỌN woli ati awọn olukọni si mbẹ ninu ijọ ti o wà ni Antioku; Barnaba, ati Simeoni ti a npè ni Nigeri, ati Lukiu ara Kirene, ati Manaeni, ti a tọ́ pọ̀ pẹlu Herodu tetrarki, ati Saulu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn wòlíì àti àwọn olùkọ́ni sì ń bẹ nínú ìjọ ti ó wà ni Áńtíókù; Bánábà àti Síméónì tí a ń pè ni Nígérì, àti Lúkíọ́sì ará Kírénè, àti Mánáénì (ẹni tí a tọ́ pọ̀ pẹ̀lú Hẹ́ródù Tétírákì) àti Ṣọ́ọ̀lù.