Acts 13:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn tí wọ́n ti ka Ìwé Mímọ́, láti inú Ìwé Òfin Mose ati Ìwé àwọn wolii, àwọn olóyè ilé ìpàdé àwọn Juu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin arakunrin, bí ẹ bá ní ọ̀rọ̀ ìyànjú fún àwọn eniyan, ẹ sọ ọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati lẹhin kìka iwe ofin ati iwe awọn woli, awọn olori sinagogu ranṣẹ si wọn, pe, Ará, bi ẹnyin ba li ọ̀rọ iyanju kan fun awọn enia, ẹ sọ ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn kíka ìwé òfin àti ìwé àwọn wòlíì, àwọn olórí sínágọ́gù ránṣẹ́ sí wọn, pé, “Ará, bí ẹ̀yin bá ni ọ̀rọ̀ ìyànjú kan fún àwọn ènìyàn, ẹ sọ ọ́!”