Acts 13:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn tí ó ń gbé Jerusalẹmu ati àwọn olóyè wọn, wọn kò mọ ẹni tí Jesu jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ohun tí àwọn wolii ń sọ kò yé wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n ń kà á. Wọ́n mú àkọsílẹ̀ wọnyi ṣẹ nígbà tí wọ́n dá a lẹ́bi ikú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori awọn ti ngbe Jerusalemu, ati awọn olori wọn, nitoriti nwọn kò mọ̀ ọ, ati ọ̀rọ awọn woli, ti a nkà li ọjọjọ isimi, kò yé wọn, nwọn mu u ṣẹ ni didajọ rẹ̀ lẹbi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí àwọn tí ń gbé Jerúsálémù, àti àwọn olórí wọn, nítorí ti wọn kò mọ̀ Jésù, tí wọn kò sì ní òye ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì, tí a ń kà ní ọjọọjọ́ ìsinmi fún wọn, kò yé wọn, wọ́n mú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yìí ṣẹ nípa dídá a lẹ́bi.