Acts 13:43 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ìpàdé túká, ọpọlọpọ àwọn Juu ati àwọn tí wọ́n ti di ẹlẹ́sìn àwọn Juu ń tẹ̀lé Paulu ati Banaba. Àwọn òjíṣẹ́ mejeeji yìí tún ń bá wọn sọ̀rọ̀, wọ́n ń gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n dúró láì yẹsẹ̀ ninu oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn si jade ni sinagogu, ọ̀pọ ninu awọn Ju ati ninu awọn olufọkansìn alawọṣe tẹle Paulu on Barnaba: awọn ẹniti o ba wọn sọ̀rọ ti nwọn si rọ̀ wọn lati duro ninu ore-ọfẹ Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọn sì jáde nínú sínágọ́gù, ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù àti nínú àwọn olùfọkànsìn aláwọ̀ṣe Júù tẹ̀le Pọ́ọ̀lù àti Básébà, àwọn ẹni tí ó bá wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì rọ̀ wọ́n láti dúró nínú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.