Acts 13:50 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn Juu rú àwọn gbajúmọ̀ obinrin olùfọkànsìn sókè, ati àwọn eniyan pataki-pataki ní ìlú, ni wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí Paulu ati Banaba. Wọ́n lé wọn jáde kúrò ní agbègbè wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn Ju rú awọn obinrin olufọkansin ati ọlọlá soke ati awọn àgba ilu na, nwọn si gbe inunibini dide si Paulu on Barnaba, nwọn si ṣí wọn kuro li àgbegbe wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwọn Júù rú àwọn obìnrin olùfọkànsìn àti ọlọ́lá sókè àti àwọn àgbà ìlú náà, wọ́n sì gbé inúnibíni dìde sí Pọ́ọ̀lù àti Básébà, wọ́n sì ṣí wọn kúrò ni agbégbé wọn.