Acts 14:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní òde kí á tó wọ odi ìlú ni tẹmpili Seusi wà. Baba olórìṣà Seusi bá mú mààlúù ati òdòdó jìngbìnnì, òun ati ọpọlọpọ èrò, wọ́n ń bọ̀ lẹ́nu odi ìlú níbi tí pẹpẹ Seusi wà, wọ́n fẹ́ wá bọ wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Alufa Jupiteri ti ile oriṣa rẹ̀ wà niwaju ilu wọn, si mu malu ati màriwo wá si ẹnubode, on iba si rubọ pẹlu awọn enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àlùfáà Júpítérì, ẹni ti ilé òrìsà rẹ̀ wá lẹ́yìn odi ìlú wọn, ó sì mú màlúù àti màrìwò wá sí ẹnu-ibode láti rúbọ pẹ̀lú ìjọ ènìyàn sí àwọn àpósítélì wọ̀nyí.