Acts 14:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Paulu ati Banaba pẹ́ níbẹ̀. Wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní gbangba, ẹ̀rù kò sì bà wọ́n nítorí wọ́n gbójú lé Oluwa tí ó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ nípa iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ń ti ọwọ́ wọn ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina nwọn gbe ibẹ̀ pẹ, nwọn nfi igboiya sọrọ ninu Oluwa, ẹniti o jẹri si ọ̀rọ ore-ọfẹ rẹ̀, o si nyọnda ki iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu mã ti ọwọ́ wọn ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà Pọ́ọ̀lù àti Bánábà gbé ibẹ̀ pẹ́, wọ́n ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nínú Olúwa, ẹni tí ó jẹ̀rìí sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, ó sì yọ̀ǹda kí iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu máa ti ọwọ́ wọn ṣe.