Acts 15:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó di ọ̀rọ̀ líle ati àríyànjiyàn ńlá láàrin àwọn ati Paulu ati Banaba. Ni ìjọ bá pinnu pé kí Paulu ati Banaba ati àwọn mìíràn láàrin wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli ati àwọn alàgbà ní Jerusalẹmu láti yanjú ọ̀rọ̀ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati iyapa ati iyàn jijà ti mbẹ lãrin Paulu on Barnaba kò si mọ ni ìwọn, awọn arakunrin yàn Paulu on Barnaba, ati awọn miran ninu wọn, ki nwọn goke lọ si Jerusalemu, sọdọ awọn aposteli ati awọn àgbagba nitori ọ̀ran yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánabà ni ìyapa àti ìyàn jíjà tí kò mọ níwọ̀n pẹ̀lú wọn, wọ́n yan Pọ́ọ̀lù àti Bánábà àti àwọn mìíràn nínú àpósítélì kí wọn gòkè lọ sí Jerúsálémù, sọ́dọ̀ àwọn alàgbà nítorí ọ̀ràn yìí.