Acts 15:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn aposteli ati àwọn àgbà ìjọ pẹlu gbogbo ìjọ wá pinnu láti yan àwọn eniyan láàrin wọn, láti rán lọ sí Antioku pẹlu Paulu ati Banaba. Wọ́n bá yan Juda tí à ń pè ní Basaba ati Sila, tí wọn jẹ́ aṣaaju láàrin àwọn onigbagbọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li o tọ́ loju awọn aposteli, ati awọn àgbagbà pẹlu gbogbo ijọ, lati yàn enia ninu wọn, ati lati ran wọn lọ si Antioku pẹlu Paulu on Barnaba: Juda ti a npè apele rẹ̀ ni Barsaba, ati Sila, ẹniti o l'orukọ ninu awọn arakunrin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà nàá ni ó tọ́ lójú àwọn àpósítélì, àti àwọn alàgbà pẹ̀lú gbogbo ìjọ, láti yan ènìyàn nínú wọn, àti láti rán wọ́n lọ sí Áńtíókù pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù àti Bánábà: Júdà ti a ń pè àpèlé rẹ̀ ní Básábà, àti Sílà, ẹni tí ó lórúkọ nínú àwọn arákùnrin.