Acts 15:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn kan láti inú ẹgbẹ́ àwọn Farisi tí wọ́n jẹ́ onigbagbọ wá dìde. Wọ́n ní, “Dandan ni pé kí á kọ àwọn tí kì í ṣe Juu tí ó bá fẹ́ di onigbagbọ nílà, kí á sì pàṣẹ fún wọn láti máa pa Òfin Mose mọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn kan ti ẹya awọn Farisi ti nwọn gbagbọ́ dide, nwọn nwipe, a ni lati kọ wọn ni ilà, ati lati paṣẹ fun wọn pe ki nwọn ki o mã pa ofin Mose mọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwọn kan ti ẹ̀yà àwọn Farisí tí wọ́n gbàgbọ́ dìde, wọ́n ń wí pé, “A ní láti kọ wọ́n ní ilà, àti láti pàṣẹ fún wọn pé kí wọn máa pa òfin Mósè mọ́.”