Acts 16:37 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn Paulu sọ fún wọn pé, “Wọ́n nà wá ní gbangba láì ká ẹ̀bi mọ́ wa lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni wá. Wọ́n sọ wá sẹ́wọ̀n, wọ́n wá fẹ́ tì wá jáde níkọ̀kọ̀. Rárá o! Kí àwọn fúnra wọn wá kó wa jáde.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Paulu wi fun wọn pe, Nwọn lù wa ni gbangba, nwọn si sọ wa sinu tubu li aijẹbi, awa ẹniti iṣe ara Romu: nisisiyi nwọn si fẹ ti wa jade nikọ̀kọ? agbẹdọ; ṣugbọn ki awọn tikarawọn wá mu wa jade.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù wí fún wọn pé, “Wọ́n lù wá ni gbangba, wọ́n sì sọ wá sínú túbú ni àìjẹ̀bí, àwa ẹni tí ì ṣe ara Róòmù: ṣe nísinsìnyìí wọ́n fẹ́ tì wá jáde nikọ̀kọ̀? Àgbẹdọ̀! Ṣùgbọ́n kí àwọn tìkara wọn wá mú wa jáde!”