Acts 17:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn yìí ṣe onínú rere ju àwọn Juu ti Tẹsalonika lọ. Wọ́n fi ìtara gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Lojoojumọ ni wọ́n ń wá inú Ìwé Mímọ́ wò láti rí bí àwọn ohun tí wọ́n kọ́ wọn rí bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn wọnyi si ni iyìn jù awọn ti Tessalonika lọ, niti pe nwọn fi tọkantọkan gbà ọ̀rọ na, nwọn si nwá inu iwe-mimọ́ lojojumọ́ bi nkan wọnyi ri bẹ̃.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn wọ̀nyí sì ní ìyìn ju àwọn tí Tẹsalóníkà lọ, ní tí pé wọn fi tọkàntọkàn gbà ọ̀rọ̀ náà. Wọ́n sì ń wá inú ìwé-mímọ̀ lójoojúmọ́ bí ǹkan wọ̀nyí bá rí bẹ́ẹ̀.