Acts 17:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Paulu ń dúró dè wọ́n ní Atẹni, ó rí ìlú náà bí ó ti kún fún ère oriṣa. Eléyìí sì dùn ún dọ́kàn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Paulu duro dè wọn ni Ateni, ọkàn rẹ̀ rú ninu rẹ̀, nigbati o ri pe ilu na kún fun oriṣa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù dúró dè wọ́n ni Aténì, ẹ̀mí rẹ̀ ru nínú rẹ̀, nígbà tí ó rí pé ìlú náà kún fún òrìṣà.