Acts 17:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, ó ń bá àwọn Juu ati àwọn olùfọkànsìn tí kì í ṣe Juu jiyàn ninu ilé ìpàdé ní ojoojumọ. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó ń ṣe láàrin ọjà, ó ń bá ẹnikẹ́ni tí ó bá wà nítòsí sọ̀rọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina o mba awọn Ju fi ọ̀rọ̀ we ọ̀rọ̀ ninu sinagogu, ati awọn olufọkansin, ati awọn ti o mba pade lọja lojojumọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà ó ń bá àwọn Júù fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú Sínágógù, àti àwọn olùfọkànsìn, àti àwọn tí ó ń bá pàdé lọ́jà lójoojúmọ́.