Acts 17:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí ẹnìkan sọ níbìkan pé: ‘Ninu rẹ̀ ni à ń gbé, tí à ń rìn kiri, tí a wà láàyè.’ Àwọn kan ninu àwọn akéwì yín pàápàá ti sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀; wọ́n ní, ‘Ọmọ rẹ̀ ni a jẹ́.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ninu rẹ̀ li awa gbé wà li ãye, ti awa nrìn kiri, ti a si li ẹmí wa; bi awọn kan ninu awọn olorin, ẹnyin tikaranyin ti wipe, Awa pẹlu si jẹ ọmọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí nínú rẹ̀ ni àwa wà láàyè, tí a ń rìn kiri, tí a sì ní ẹ̀mí wa: bí àwọn kan nínú àwọn akéwì tí ẹ̀yin tìkarayín tí wí pé, ‘Àwa pẹ̀lú sì jẹ́ ọmọ rẹ̀.’