Acts 17:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ń ṣe àlàyé fún wọn, ó tún ń tọ́ka sí àkọsílẹ̀ inú Ìwé Mímọ́ láti fihàn pé dandan ni kí Mesaya jìyà, kí ó jinde kúrò ninu òkú. Lẹ́yìn náà ó sọ fún wọn pé, Mesaya yìí náà ni Jesu tí òun ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O ntumọ, o si nfihàn pe, Kristi kò le ṣaima jìya, ki o si jinde kuro ninu okú; ati pe, Jesu yi, ẹniti emi nwasu fun nyin, on ni Kristi na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó ń túmọ̀, ó sí n fihàn pé, Kíríṣítì kò lè sàìmá jìyà, kí o sì jínde kúrò nínú òkú; àti pé, “Jéṣu yìí ẹni tí èmi ń wàásù fún yin, òun ni Kírísítì náà.”