Acts 17:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí ó ti yan ọjọ́ tí yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ gbogbo ayé nípa ọkunrin tí ó ti yàn. Ó fi òtítọ́ èyí han gbogbo eniyan nígbà tí ó jí ẹni náà dìde kúrò ninu òkú.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Niwọnbi o ti da ọjọ kan, ninu eyi ti yio ṣe idajọ aiye li ododo, nipasẹ ọkunrin na ti o ti yàn, nigbati o ti fi ohun idaniloju fun gbogbo enia, niti o jí i dide kuro ninu okú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Níwọ̀n bí ó ti dá ọjọ́ kan, nínú èyí tí yóò ṣe ìdájọ́ ayé lódodo nípaṣẹ̀ ọkùnrin náà tí ó ti yàn, nígbà tí ó ti fi ohun ìdánilójú fún gbogbo ènìyàn, níti pé ó jí dìde kúrò nínú òkú.”