Acts 17:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn ara ta àwọn Juu nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn eniyan pupọ gba ọ̀rọ̀ Paulu ati Sila. Wọ́n bá lọ mú ninu àwọn tí wọ́n ń fẹsẹ̀ wọ́lẹ̀ kiri, àwọn jàgídíjàgan, wọ́n kó wọn jọ. Wọ́n bá dá ìrúkèrúdò sílẹ̀ ninu ìlú. Wọ́n lọ ṣùrù bo ilé Jasoni, wọ́n ń wá Paulu ati Sila kí wọ́n lè fà wọ́n lọ siwaju àwọn ará ìlú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn Ju jowu, nwọn si fà awọn jagidijagan ninu awọn ijajẹ enia mọra, nwọn gbá ẹgbẹ jọ, nwọn si nrú ilu; nwọn si kọlù ile Jasoni, nwọn nfẹ mu wọn jade tọ̀ awọn enia wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwọn Júù jowú, wọn si fa àwọn jàgídíjàgan nínú àwọn ọmọ ìta ènìyàn mọ́ra, wọ́n gbá ẹgbẹ́ jọ, wọ́n sì ń dá ìlú rú; wọ́n sì kọlu ilé Jásónì, wọ́n ń fẹ́ láti mú wọn jáde tọ àwọn ènìyàn lọ.