Acts 18:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ni gbogbo wọ́n bá mú Sositene, olórí ilé ìpàdé àwọn Juu, wọ́n ń lù ú níwájú kóòtù. Ṣugbọn Galio kò pé òun rí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn Hellene si mu Sostene, olori sinagogu, nwọn si lù u niwaju itẹ idajọ. Gallioni kò si ṣú si nkan wọnyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn Gíríkì sì mú Sósìténì, olórí ṣínágógù, wọ́n sì lù ú níwájú ìtẹ́ ìdájọ́. Gálíónì kò sì bìkítà fún nǹkan wọ̀nyí.