Acts 18:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó rí Juu kan níbẹ̀, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Akuila, ará Pọntu. Òun ati Pirisila iyawo rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ Itali dé ni, nítorí ọba Kilaudiu pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn Juu kúrò ní ìlú Romu. Paulu bá lọ sọ́dọ̀ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ri Ju kan ti a npè ni Akuila, ti a bí ni Pontu, ti o ti Itali de nilọ̃lọ̃, pẹlu Priskilla aya rẹ̀; nitoriti Klaudiu paṣẹ pe, ki gbogbo awọn Ju ki o jade kuro ni Romu: o si tọ̀ wọn wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì rí Júù kan tí a ń pè ní Àkúílà, tí a bí ni Pọ́ńtù, tí ó ti Ìtalì dé ní lọ́ọ́lọ́ọ́, pẹ̀lú Pírísíkílà aya rẹ̀; nítorí tí Kíláúdíù pàsẹ pé, kí gbogbo àwọn Júù jáde kúrò ní Róòmù. Ó sì tọ̀ wọ́n lọ láti rí wọn.