Acts 18:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
A ti fi ọ̀nà Oluwa kọ́ ọ, a máa sọ̀rọ̀ pẹlu ìtara; a sì máa kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ nípa Jesu ní àkọ́yé. Ṣugbọn ìrìbọmi tí Johanu ṣe nìkan ni ó mọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkunrin yi li a ti kọ́ ni ọ̀na ti Oluwa; o si ṣe ẹniti o gboná li ọkàn, o nfi ãyan nsọ̀rọ, o si nkọ́ni ni nkan ti Oluwa; kìki baptismu ti Johanu li o mọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọkùnrin yìí ni a tí kọ́ ní ọ̀nà tí Olúwa; ó sì ṣe ẹni tí ó ní ìtara tí ẹ̀mí, ó ń sọ̀rọ̀ ó sì ń kọ́ni ní àwọn ohun tí i ṣe ti Olúwa dáradára; kìkì bamitíìsímù tí Jòhánù ní ó mọ̀.