Acts 18:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ pẹlu ìgboyà ninu ilé ìpàdé àwọn Juu. Nígbà tí Pirisila ati Akuila gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n mú un, wọ́n túbọ̀ fi ọ̀nà Ọlọrun yé e yékéyéké.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si bẹ̀rẹ si fi igboiya sọrọ ni sinagogu: nigbati Akuila on Priskilla ti gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, nwọn mu u si ọdọ nwọn si tubọ sọ idi ọ̀na Ọlọrun fun u dajudaju.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì bẹ̀rẹ̀ ṣí fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ni Sínágọ́gù: nígbà tí Àkúílà àti Pìrìskílà gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n mú un sọ́dọ̀ wọ́n sì túbọ̀ sọ ọ̀nà Ọlọ́run fún un dájúdájú.