Acts 18:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó fẹ́ kọjá lọ sí Akaya, àwọn onigbagbọ ní Efesu fún un ní ìwúrí, wọ́n kọ ìwé sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní Akaya pé kí wọ́n gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀. Nígbà tí Apolo dé Akaya, ó wúlò lọpọlọpọ fún àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ níbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si nfẹ kọja lọ si Akaia, awọn arakunrin gba a ni iyanju, nwọn si kọwe si awọn ọmọ-ẹhin ki nwọn ki o gba a: nigbati o si de, o ràn awọn ti o gbagbọ́ nipa ore-ọfẹ lọwọ pupọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó sì ń fẹ́ kọjá lọ sì Ákáyà, àwọn arakùnrin gbà á ní ìyànjú, wọ́n sì kọ̀wé sí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn kí wọ́n gbà á: nígbà tí ó sì dé, ó ràn àwọn tí ó gbàgbọ́ nípasẹ̀ oore-ọfẹ lọ́wọ́ púpọ̀,