Acts 19:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo àwọn Juu ati àwọn Giriki tí ó ń gbé Efesu ni wọ́n gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí. Ẹ̀rù ba gbogbo wọn; wọ́n sì gbé orúkọ Jesu Oluwa ga.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ihìn yi si di mimọ̀ fun gbogbo awọn Ju ati awọn ara Hellene pẹlu ti o ṣe atipo ni Efesu; ẹ̀ru si ba gbogbo wọn, a si gbé orukọ Jesu Oluwa ga.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìròyìn yìí sì di mímọ̀ fún gbogbo àwọn Júù àti àwọn ará Gíríkì pẹ̀lú tí ó ṣe àtìpó ní Éfésù; ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn, a sì gbé orúkọ Jésù Olúwa ga.