Acts 19:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, Paulu pinnu lọ́kàn rẹ̀ láti gba Masedonia lọ sí Akaya, kí ó wá ti ibẹ̀ lọ sí Jerusalẹmu. Ó ní, “Nígbà tí mo bá dé ibẹ̀, ó yẹ kí n fojú ba Romu náà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ bi nkan wọnyi ti pari tan, Paulu pinnu rẹ̀ li ọkàn pe, nigbati on ba kọja ni Makedonia ati Akaia, on ó lọ si Jerusalemu, o wipe, Lẹhin igba ti mo ba de ibẹ̀, emi kò le ṣaima ri Romu pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ bí nǹkan wọ̀nyí tí parí tan, Pọ́ọ̀lù pínnu nínú ẹ̀mí rẹ̀ pé, nígbà tí òun bá kọjá ní Makedóníà àti Ákáyà, òun ó lọ sí Jerúsálémù, ó wí pé, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo bá dé ibẹ̀, èmi kò lè ṣàì má dé Róòmù pẹ̀lú.”