Acts 19:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ wá rí i, ẹ tún ti gbọ́ pé kì í ṣe ní Efesu nìkan ni, ṣugbọn ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé ní gbogbo Esia ni Paulu yìí ti ń yí ọ̀pọ̀ eniyan lọ́kàn pada. Ó ní àwọn ohun tí a fọwọ́ ṣe kì í ṣe oriṣa!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin si ri, ẹ si gbọ́ pe, kì iṣe ni Efesu nikanṣoṣo ni, ṣugbọn o fẹrẹ ṣe gbogbo Asia, ni Paulu yi nyi ọ̀pọ enia li ọkàn pada, ti o si ndari wọn wipe, Ohun ti a fi ọwọ́ ṣe, kì iṣe ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin sì rí i, ẹ sì gbọ́ pé, kì í ṣe ni Éfésù nìkanṣoṣo ni, ṣùgbọ́n ó fẹrẹ jẹ́ gbogbo Éṣíà, ni Pọ́ọ̀lù yìí ń yí ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́kàn padà, tí ó sì ń dárí wọn wí pé, ohun tí a fi ọwọ́ ṣe, kì í ṣe Ọlọ́run.