Acts 19:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ewu wà fún wa pé, iṣẹ́ wa yóo di ohun tí eniyan kò ní kà sí mọ́. Ṣugbọn èyí nìkan kọ́, ewu tí ó tún wà ni pé, ilé ìsìn oriṣa ńlá wa, Atẹmisi, yóo di ohun tí ẹnikẹ́ni kò ní ṣújá mọ́. Láìpẹ́ kò sí ẹni tí yóo gbà pé oriṣa wa tóbi mọ́, oriṣa tí gbogbo Esia ati gbogbo àgbáyé ń sìn!”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki si iṣe pe kìki iṣẹ-ọnà wa yi li o wà li ewu ati di asan; ṣugbọn ile Diana oriṣa nla yio si di gigàn pẹlu, ati gbogbo ọla nla rẹ̀ yio si run, ẹniti gbogbo Asia ati gbogbo aiye mbọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kì í sì ṣe pé kìkí iṣẹ́-ọnà wa yìí ni ó wà nínú ewu dídí aṣán; ṣùgbọ́n ilé Dáyánà òrìṣà ńlá yóò di gígàn pẹ̀lú, àti gbogbo ọlá-ńlá rẹ̀ yóò sì run, ẹni tí gbogbo Éṣíà àti gbogbo ayé ń bọ.”