Acts 19:35 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Akọ̀wé ìgbìmọ̀ ìlú ló mú kí wọ́n dákẹ́. Ó wá sọ pé, “Ẹ̀yin ará Efesu, ta ni kò mọ̀ pé ìlú Efesu ni ó ń tọ́jú ilé ìsìn Atẹmisi oriṣa ńlá, ati òkúta rẹ̀ tí ó bọ́ sílẹ̀ láti ọ̀run?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati akọwe ilu si mu ki ijọ enia dakẹ, o ni, Ẹnyin ará Efesu, tali ẹniti o wà ti kò mọ̀ pe, ilu ara Efesu ni iṣe olusin Diana oriṣa nla, ati ti ere ti o ti ọdọ Jupiteri bọ́ silẹ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí akọ̀wé ìlú sì mú kí ìjọ ènìyàn dákẹ́, ó ní, “Ẹ̀yin ará Éfésù, ta ni ẹni tí ó wà tí kò mọ̀ pé, ìlú ará Éfésù ní í ṣe olùsìn Dáyánà òrìṣà ńlá, àti tí ère tí ó ti ọ̀dọ̀ Júpítérì bọ́ sílẹ̀?